translation
dict |
---|
{
"en": "We are pleased that on November 18, 2019, the Norwegian officials ruled that Jehovah’s Witnesses should continue to receive State grants, concluding:",
"eng": null,
"yor": "Inú wa dùn pé ní November 18, ọdún 2019, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Norway sọ pé ìjọba gbódọ̀ máa fi owó ṣètìlẹyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí wọ́n fi parí ọ̀rọ̀ wọn ni pé:"
} |
{
"en": "“Voting in elections is a fundamental right for Norwegian citizens, but not an obligation.",
"eng": null,
"yor": "“Ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè Norway ló jẹ́ láti dìbò nígbà ìdìbò, àmọ́ kì í ṣe tipátipá fẹ́ni tí kò bá wù."
} |
{
"en": "Abstaining from this right seems to be part of the beliefs of Jehovah’s Witnesses, . . . [but the government] cannot see that this . . . provides a legally sustainable basis for withdrawing state grants.”",
"eng": null,
"yor": "Ó jọ pé lára ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ni pé kò yẹ káwọn máa dìbò, . . . [ṣùgbọ́n] kò wá yẹ kí [ìjọba] rí èyí bí . . . ìdí tó bófin mu láti má ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní owó tí ìjọba fi ń ṣètìlẹ́yìn.”"
} |
{
"en": "Regarding these decisions, Brother Dag-Erik Kristoffersen, from the Scandinavia branch, states:",
"eng": null,
"yor": "Nígbà tí Arákùnrin Dag-Erik Kristoffersen, láti ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Scandinavia, ń sọ̀rọ̀ lórí ìpinnu yìí, ó ní:"
} |
{
"en": "“We are happy that we are recognized as being a positive force in the community.",
"eng": null,
"yor": "“Inú wa dùn pé ìjọba ti wá rí i pé à ń ṣe ohun tó dáa fáwọn aráàlú."
} |
{
"en": "It is our hope that other countries that have similar arrangements take note of this ruling.”",
"eng": null,
"yor": "A nírètí pé àwọn orílẹ̀-èdè míì tí ìjọba ti ń fowó ṣètìlẹ́yìn fáwọn ẹlẹ́sìn á kíyè sí ẹjọ́ tílé ẹjọ́ dá yìí.”"
} |
{
"en": "Above all, we give thanks to Jehovah, the Supreme Lawgiver.—Isaiah 33:22.\"",
"eng": null,
"yor": "Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a fi ọpẹ́ fún Jèhófà, Afúnnilófin wa Gíga Jù Lọ.—Àìsáyà 33:22.\""
} |
{
"en": "\"On September 26, 2018, the Supreme Court of the “Donetsk People’s Republic” (DPR) declared the religious association of Jehovah’s Witnesses to be “extremist,” effectively banning our activities.",
"eng": null,
"yor": "\"Ní September 26, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní “Donetsk People’s Republic” (DPR) sọ pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni àjọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa."
} |
{
"en": "Neither the general prosecutor, who initiated the claim against our legal entity, nor the Court consulted with any of Jehovah’s Witnesses during the proceedings.",
"eng": null,
"yor": "Kò sí ìkankan nínú àwọn tó pe ẹjọ́ yìí, títí kan Ilé tó dá ẹjọ́ náà tó béèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan nígbà tí ẹjọ́ náà ń lọ lọ́wọ́."
} |
{
"en": "The banning is the latest development in an escalating pattern of religious oppression against Jehovah’s Witnesses in the region.",
"eng": null,
"yor": "Ìfòfindè yìí ni ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n gbé nínú bí wọ́n ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè yìí torí ẹ̀sìn wọn."
} |
{
"en": "The situation of our brothers in certain territories of the Donetsk and Luhansk regions, in eastern Ukraine, has deteriorated since the DPR Supreme Court declared some of our publications to be “extremist” in mid-2017.",
"eng": null,
"yor": "Láti àárín ọdún 2017 tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ nílẹ̀ DPR ti sọ pé lára àwọn ìtẹ̀jáde wa jẹ́ ti àwọn “agbawèrèmẹ́sìn,” ńṣe ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i fún àwọn ará wa láwọn agbègbè kan ní Donetsk àti Luhansk, ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Ukraine."
} |
{
"en": "During that year, police interrogated over 170 Witnesses.",
"eng": null,
"yor": "Kí ọdún yẹn tó parí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn ọlọ́pàá mú kí wọ́n lè da ìbéèrè bò wọ́n lé ní àádọ́sàn-án (170)."
} |
{
"en": "Authorities in the regions have also systematically seized Kingdom Halls.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn aláṣẹ agbègbè náà sì tún ṣètò bí wọ́n ṣe ń gba àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ní kọ̀ọ̀kan."
} |
{
"en": "As of August 29, 2018, a total of 16 Kingdom Halls have been confiscated.",
"eng": null,
"yor": "Iye gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti gbà títí di August 29, 2018 jẹ́ mẹ́rìnlélógún (16)."
} |
{
"en": "Despite these attacks on their worship, our brothers and sisters in these territories are continuing to rely on the ‘God of salvation.’—Psalm 18:46.\"",
"eng": null,
"yor": "Lójú gbogbo àtakò ẹ̀sìn yìí, àwọn ará wa láwọn agbègbè yìí gbẹ́kẹ̀ lé ‘Ọlọ́run ìgbàlà wa.’—Sáàmù 18:46.\""
} |
{
"en": "\"Jehovah’s Witnesses in Ukraine welcomed thousands of their brothers and sisters for the special convention held in Lviv, Ukraine, on July 6-8, 2018.",
"eng": null,
"yor": "\"Ní July 6 sí 8, 2018, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará káàbọ̀ síbi àkànṣe àpéjọ tó wáyé ní ìlú Lviv, lórílẹ̀-èdè Ukraine."
} |
{
"en": "Over 3,300 delegates from nine countries traveled to Ukraine, primarily to benefit from the spiritual program that featured the theme “Be Courageous”!",
"eng": null,
"yor": "Ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (3,300) èèyàn láti orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-án tó wá sí Ukraine láti wá gbádùn ètò tó dá lórí Bíbélì náà, àkòrí ètò náà ni “Jẹ́ Onígboyà”!"
} |
{
"en": "They also enjoyed the warm hospitality extended by their Ukrainian hosts.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn ará ní Ukraine sì ṣaájò wọn gan-an."
} |
{
"en": "Preparations for the convention began in April 2017, and over the next 15 months many local Witnesses volunteered to assist in arranging for the convention activities and to care for the brothers during their visit.",
"eng": null,
"yor": "Oṣù April 2017 ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún àpéjọ náà, lóṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tó tẹ̀ lé e, àwọn ará tó wà lágbègbè náà yọ̀ǹda ara wọn láti ṣètò àpéjọ náà àti bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn tó máa wá sí àpéjọ náà."
} |
{
"en": "Delegates experienced some of the unique aspects of Ukrainian culture that included dance and musical performances, and a taste of traditional food.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn tó wá síbi àpéjọ náà rí lára àwọn àṣà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn ilẹ̀ Ukraine ní, irú bí ijó àti orin wọn àtàwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn."
} |
{
"en": "Guided tours were arranged to visit a local museum, ancient castles, and to see a part of the spectacular Carpathian mountain range.",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n ṣètò báwọn èèyàn ṣe máa lọ síbi tí wọ́n ń ko àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí, àwọn ilé ńlá ayé àtijọ́ àti bí wọ́n ṣe máa lọ wo lára òkè Carpathian tó jẹ́ àwòṣífìlà."
} |
{
"en": "A special highlight was the opportunity to accompany local Ukrainian Witnesses in the field ministry.",
"eng": null,
"yor": "Ètò kan tó tún ṣàrà ọ̀tọ̀ ni báwọn tó wá ṣe láǹfààní láti bá àwọn ará ní Ukraine lọ sóde ẹ̀rí."
} |
{
"en": "The convention program originated from a large arena in Lviv, and the peak attendance was over 25,000.",
"eng": null,
"yor": "Pápá ìṣeré kan ní ìlú Lviv ni wọ́n ti ṣe àpéjọ náà, àwọn tó wá síbẹ̀ sì ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000)."
} |
{
"en": "Key portions of the program were broadcast to 15 other stadiums and numerous Kingdom Halls throughout the country, with a total attendance of over 125,000 and 1,420 baptized.",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n tàtaré àwọn apá tó jẹ́ lájorí nínú àpéjọ náà sí pápá ìṣeré mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) míì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri orílẹ̀-èdè náà, iye gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ náà lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùnlélọ́gọ́fà (125,000), àwọn ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (1,420) ló sì ṣèrìbọmi."
} |
{
"en": "Ivan Riher, a representative at the branch office in Ukraine, commented: “We greatly anticipated this special event and the chance to welcome our brothers and sisters from other countries.",
"eng": null,
"yor": "Ivan Riher tó jẹ́ aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Ukraine, sọ pé: “A ti ń fojú sọ́nà fún àpéjọ pàtàkì yìí, ó sì ń wù wá láti kí àwọn ará láti àwọn orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀."
} |
{
"en": "We enjoyed extending Ukrainian hospitality to our visitors and felt that the unity and courage among our global family of worshippers was strengthened.”—Psalm 133:1.\"",
"eng": null,
"yor": "A gbádùn bí a ṣe fi àwọn nǹkan ilẹ̀ wa ṣe àwọn tó wá lálejò, èyí sì mú ká rí bí ìṣọ̀kan àti ìgboyà tó wà láàárín àwọn ará wa kárí ayé ṣe ń pọ̀ sí i.”—Sáàmù 133:1.\""
} |
{
"en": "\"Jehovah’s Witnesses in Ukraine hosted special Bible exhibitions to highlight the release of the New World Translation of the Christian Greek Scriptures in Russian Sign Language (RSL), a major milestone in our translation efforts.",
"eng": null,
"yor": "\"Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine ṣe àfihàn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a mú jáde ní Èdè Adití ti Rọ́síà, aṣeyọrí tó lápẹẹrẹ lèyí sì jẹ́ nínú iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí à ń ṣe."
} |
{
"en": "The exhibitions began on October 7, 2018, in Lviv and continued through June 7, 2019. Other host cities included Kharkiv, Kyiv, Odesa, and Dnipro.",
"eng": null,
"yor": "Àfihàn náà bẹ̀rẹ̀ ní October 7, 2018 ní ìlú Lviv, a sì ṣe é títí di June 7, 2019. Àwọn ìlú míì tá a ti ṣe àfihàn náà ni Kharkiv, Kyiv, Odesa àti Dnipro."
} |
{
"en": "Prior to each event, local sign-language congregations distributed both printed and video invitations to deaf and hard-of-hearing people in the areas where the exhibition would be hosted.",
"eng": null,
"yor": "Kí a tó ṣe àfihàn yìí, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè adití pín ìwé ìkésíni fáwọn adití àtàwọn tí kò gbọ́ran dáadáa lágbègbè tí àfihàn náà ti máa wáyé, wọ́n sì tún fàwọn fídíò hàn wọ́n."
} |
{
"en": "Additionally, the Public Information Desk at the Ukraine branch distributed invitations to educators, the media, and State officials.",
"eng": null,
"yor": "Yàtọ̀ síyẹn, Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde ní ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Ukraine pín ìwé ìkésíni fún àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́, àwọn oníròyìn àtàwọn aláṣẹ."
} |
{
"en": "Attendees at the first event, at the Lviv City Deaf Club, were shown the various digital tools available to the deaf for Bible study, such as the JW Library Sign Language® app.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn tó wá síbi àfihàn tá a kọ́kọ́ ṣe ní Lviv City Deaf Club rí oríṣiríṣi àwọn ètò tá a ṣe táwọn adití lè lò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, irú bí ètò JW Library Sign Language®."
} |
{
"en": "Visitors also enjoyed a historical display showcasing the various formats used for Bibles over the centuries, from scrolls to modern-day books.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn tó wá tún rí àfihàn kan tó ní oríṣiríṣi Bíbélì tí wọ́n ti lò láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún, látorí àwọn ìwé àkájọ títí dé àwọn ìwé òde òní."
} |
{
"en": "A notable feature of the exhibit was an edition of the Bible from 1927.",
"eng": null,
"yor": "Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ni Bíbélì kan tó ti wà látọdún 1927."
} |
{
"en": "We are happy that the RSL New World Translation of the Christian Greek Scriptures is now available.",
"eng": null,
"yor": "Inú wa dùn pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà ní Èdè Adití ti Rọ́síà."
} |
{
"en": "We are confident that it will help those who use RSL to gain accurate knowledge of the Scriptures.—Matthew 5:3.\"",
"eng": null,
"yor": "Ó dá wa lójú pé ó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń sọ èdè náà láti ní ìmọ̀ tó péye nípa Bíbélì.—Mátíù 5:3.\""
} |
{
"en": "\"The construction of the Britain branch office near Chelmsford, Essex, is projected to be completed in December 2019.",
"eng": null,
"yor": "\"Iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wà nítòsí Chelmsford, Essex ni a retí pé kó parí ní December 2019."
} |
{
"en": "Already, it is recognized by secular experts as an example of land rejuvenation.",
"eng": null,
"yor": "Ní báyìí, àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé àpẹẹrẹ tó yẹ kí àwọn èèyàn tẹ̀ lé tó bá di pé ká sọ ilẹ̀ dọ̀tun ló jẹ́."
} |
{
"en": "When our brothers purchased the property in 2015, it was a vehicle scrap heap and an unregulated dump site.",
"eng": null,
"yor": "Oríṣiríṣi pàǹtírí làwọn èèyàn ń dà sí ilẹ̀ ọ̀hún títí kan àwọn mọ́tò tó ti bà jẹ́ kí àwọn ará wa tó ra ilẹ̀ náà ní 2015."
} |
{
"en": "Volunteers unearthed and recycled large quantities of waste material, including thousands of tires—some dating back to World War II.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ló hú àwọn ìdọ̀tí náà kúrò, wọ́n kó o dà nù, wọ́n sì tún àwọn kan tó ṣì lè wúlò ṣe, wọ́n tiẹ̀ hú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn táyà tọ́jọ́ wọ́n ti pẹ́ jáde níbẹ̀, kódà àwọn táyà kan ti wà níbẹ̀ látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì."
} |
{
"en": "Then they sifted through the contaminated soil to remove even small pieces of debris, and recycled or repurposed the debris when possible, reusing the soil on the site.",
"eng": null,
"yor": "Lẹ́yìn náà, wọ́n sẹ́ àwọn iyanrìn tó ti dọ̀tí, títí kan àwọn òkúta kéékèèké, wọ́n sì tún wọ́n ṣe fún lílò, wọ́n tiẹ̀ tún àwọn kan ṣe kí wọ́n lè lò wọ́n fún àwọn nǹkan míì, kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún lo àwọn iyanrìn tó mọ́ náà fún iṣẹ́ ìkọ́lé."
} |
{
"en": "Ultimately, more than 11,000 brothers and sisters have volunteered over four million hours to help restore the 34-hectare (approx. 85 a.) property.",
"eng": null,
"yor": "Ní àkópọ̀, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá (11,000) àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó sì ju mílíọ̀nù mẹ́rin wákàtí lọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ hẹ́kítà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n náà."
} |
{
"en": "Left: Trained volunteers clear the site of debris in 2015; Right: A recent image of the attractive botanical garden",
"eng": null,
"yor": "Òsì: Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ń kó àwọn ìdọ̀tí tó wà nílẹ̀ náà kúrò lọ́dún 2015; Ọ̀tún: Fọ́tò ọ̀kan lára ọgbà tí wọ́n gbin onírúurú òdòdó sí"
} |
{
"en": "The finished property will include native and botanical gardens, ponds, wildflower meadows, and an orchard.",
"eng": null,
"yor": "Tí wọ́n bá parí iṣẹ́ náà, ilẹ̀ náà máa ní ọgbà ọ̀gbìn tó rẹwà, adágún omi, onírúurú òdòdó ẹgàn àti ọgbà eléso tó jojú ní gbèsè."
} |
{
"en": "The landscape design goes beyond aesthetics.",
"eng": null,
"yor": "Kì í ṣe pé ilẹ̀ tó tẹ́jú yìí kàn dùn ún wò nìkan ni."
} |
{
"en": "It also provides homes for native wildlife, manages surface water sustainably, preserves mature trees and hedgerows, increases native plant numbers, and beautifies the area for local residents.",
"eng": null,
"yor": "Ó tún jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹranko ìgbẹ́, ó mú kó rọrùn láti ṣọ́ omi lò, ibẹ̀ tún jẹ ibi tó dáa láti dá àwọn igi ńláńlá àti kéékèèké sí, èyí sì mú kí àwọn ewéko tó pọ̀ wà níbẹ̀, kó sì túbọ̀ mú kí àdúgbò náà rẹwà fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀."
} |
{
"en": "Brother Paul Rogers, a member of the Construction Project Committee (CPC), says: “The property we purchased had been neglected and abused for many years.",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Paul Rogers, tó jẹ́ ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ ìkọ́lé sọ pé: “Ilẹ̀ ti wọ́n ò lò, tí wọ́n sì ti pa tì fún ọ̀pọ̀ ọdún la rà."
} |
{
"en": "The transformation of the site began with an army of willing volunteers painstakingly sorting through the waste.",
"eng": null,
"yor": "Ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí jọjú nígbà tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń fara balẹ̀ ṣa àwọn ìdọ̀tí náà."
} |
{
"en": "The cleanup phase was followed by shaping and profiling the land in harmony with the existing natural features of the site, along with the planting of hundreds of new trees, bushes, and other plants.",
"eng": null,
"yor": "Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ àwọn ìdọ̀tí náà mọ́, wọ́n ń tún ilẹ̀ náà ṣe ní ìbámu pẹ̀lú bí ilẹ̀ náà ṣe rí, wọ́n wá gbin onírúurú àwọn igi, igbó àtàwọn ewéko."
} |
{
"en": "The beautiful end result echoes the words of Ezekiel 36:35, 36: ‘And people will say: “The desolate land has become like the garden of Eden” . . .",
"eng": null,
"yor": "Bí ilẹ̀ náà ṣe rẹwà lẹ́yìn tí wọ́n tún un ṣe rán wa létí ọ̀rọ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 36:35, 36 tó sọ pé: ‘Àwọn èèyàn á sì sọ pé: “Ilẹ̀ tó ti di ahoro náà ti dà bí ọgbà Édẹ́nì” . . ."
} |
{
"en": "And the nations . . . will have to know that I myself, Jehovah, have built what was torn down, and I have planted what was desolate.’”",
"eng": null,
"yor": "Àwọn orílẹ̀-èdè . . . yóò wá mọ̀ pé, èmi Jèhófà ti kọ́ ohun tó ya lulẹ̀, mo sì ti gbin ohun tó ti di ahoro.’ ”"
} |
{
"en": "The cover story for the March 2019 edition of Construction Manager magazine, the highest circulated construction-based publication in the United Kingdom, focused on the Chelmsford construction project.",
"eng": null,
"yor": "Ojú ìwé àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn tó máa ń sọ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé, tí wọ́n pín kiri jù lọ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń pè ní Construction Manager tó jáde lóṣù March 2019 sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní Chelmsford."
} |
{
"en": "The article highlights the diversity and spirit of the volunteer workforce.",
"eng": null,
"yor": "Àpilẹ̀kọ náà sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá."
} |
{
"en": "For example, the magazine notes that more young people and women contributed to the construction in comparison to a typical construction site.",
"eng": null,
"yor": "Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn náà kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ níbí iṣẹ́ ìkọ́lé náà, èyí sì yàtọ̀ sí bó ṣe máa ń rí láwọn ibi iṣẹ́ ìkọ́lé míì."
} |
{
"en": "“Everybody is happy here,” the article states, observing that overseers are greeted with waves, handshakes, and hugs.",
"eng": null,
"yor": "Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, “Ṣe ni inú gbogbo wọn ń dùn ṣìnkìn níbí,” ó tún sọ síwájú sí i nípa bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe ń kí alábòójútó wọn, àwọn òṣìṣẹ́ kan ń juwọ́, àwọn míì ń bọ̀ wọn lọ́wọ́ nígbà tó jẹ́ pé ṣe làwọn míì ń gbá wọn mọ́ra pàápàá."
} |
{
"en": "Brother Stephen Morris, who serves on the CPC, explains:",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Stephen Morris, tó jẹ́ ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ ìkọ́lé náà sọ pé:"
} |
{
"en": "“While our aim in building a new branch property is not to achieve acclaim, the professional recognition we have received is testimony to the organization and diligence of everyone involved in the project.",
"eng": null,
"yor": "“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí pé káwọn èèyàn lè kan sáárá sí wa la ṣé ń kọ́ ẹ̀ka tuntun náà, ohun táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ sọ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé náà jẹ́ ẹ̀rí pé gbogbo àwọn tó kópa nínú iṣẹ́ náà wà létòlétò, wọ́n sì já fáfá."
} |
{
"en": "All recognition ultimately goes to Jehovah and the Bible principles he has given us that govern our construction work.”—1 Corinthians 14:40.\"",
"eng": null,
"yor": "Jèhófà ni gbogbo ìyìn àti ọpẹ́ tọ́ sí, fún àwọn ìlànà Bíbélì tó fún wa, èyí tó mú ká lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé wa.”—1 Kọ́ríńtì 14:40.\""
} |